Ààrẹ Tinubu Ti Se Ètò Tí Ó Múná Dóko Èyí Tí Yóò Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ní Ànfààní Láti Kópa Nínú Ètò Ẹ̀kọ́
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu sọ pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gbáradì láti pèsè ètò ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro fún awọn ọmọdé pẹ̀lú dídá ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, gbígba àwọn olùkọ́ tí ó kójú òsùwọ̀n àti pípèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́
Ààrẹ sàlàyé pé ìgbésẹ̀ naa wà ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ìsèjọba rẹ̀ láti mú ayé rọrùn fún gbogbo ọmọ Naijiria
Ààrẹ sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó gba àlejò àwọn ìgbìmọ̀ adarí ẹgbẹ́ òsèlú APC ní Ọjọ́bọ̀, ní ìpínlẹ̀ Eko
Ó sàlàyé ìpinnu rẹ̀ láti tán ìsòro òsì láwùjọ, tí yóò sì pèsè iṣẹ́ àti ètò ẹ̀kọ́ tí o péye fun awọn ọ̀dọ́.