Ọmọ Asòfin tí ó ń sojú ẹkùn Ebonyi/Ohaukwu ní Ilé Asòfin Abuja, Pastor Eze Nwachukwu Eze ti fi àpò ìresì, Asọ, Ajílẹ̀ ta àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́rẹ láti se ìrànlọ́wọ́ fún wọn síwájú ọdún kérésìmesì àti ọdún tuntun
Ó pín ohun èlò náà fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú APC àti àwọn tí ó kù díẹ kààtó fún láwùjọ
Ètò náà wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Ebonyi, Ughodo
Nwachukwu salaye ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wáyé láti fi ran àwọn eniyan rẹ lọwọ siwaju ayajọ keresimesi