Lójúnà Àti Se Ìmọ́tótó Àyíká Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ìjọba Ìbílẹ̀ Méjìlá Ti Darapọ̀ Mọ́ Àwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ Tí Ó Se Síse Ìgbọ̀nsẹ̀ Sí Ìta Gbangba Léèwọ̀
Ìjọba Àpapọ̀ ti kéde ìjọba Ìbílẹ̀ méjìlá míràn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó mọ́ kangá, tí síṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí ìta gbangba dí èèwọ̀ níbẹ̀
Mínísítà Fún Ìpèsè Omi Àti Ìmọ́tótó Àyíká, Ọ̀jọ̀gbọ́n Terlumun Utsev ni ó síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà níbi ìpàdé olósooṣù lórí ìmótótó àyíká, èyí tí ó wáyé ní ìlú Abuja
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí ọ̀rọ̀ kàn ni: Kunchi, Gezawa, Ajingi, Karaye, Rimi Gado, Rano ati Albasu ti wọn wa ni ìpínlẹ̀ Kano, Kankara àti Funtua ní Ìpínlẹ̀ Katsina, Kolokuma/Opokuma ní Ìpínlẹ Bayelsa, Oshimili ní Ìpínlẹ̀ Delta ati Ikenne ni Ìpínlẹ̀ Ogun
Èyí ló mú kí òǹkà àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí kò se ìgbọ̀nsẹ̀ sí ìta gbangba jẹ́ okòó-lé-lọ́gọ̀rún dín mẹ́ta.