Ìfi Oyè Dáni Lọ́lá : Igbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Dáwọ̀ọ́ Ìdùnnú Pẹ̀lú Ààrẹ Àti Igbákejì Rẹ̀
Igbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Benjamin Kalu ti kí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Sẹ́nétọ̀ Kashim Shettima kú oríire fífi oyè dáwọn lọ́lá ní ilẹ̀ Igbo
Ìfoyèdánilọ́lá náà wáyé ní ọjọ́ Abámẹ́ta níbi ayẹyẹ ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ti Ukpo Ofala èyí tí Alayeluwa, Igwe Robert Chukwudilim Eze (Okofia VI) Igwe Ukpo se, ní ìjọba ìbílẹ̀ Dunukofia, Ipinlẹ Anambra
Ààrẹ, ẹnití igbákejì rẹ̀ sojú fún gba oyè “Eze Udo Igbo Land” tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó fi àlàáfíà jọba ní ilẹ̀ Igbo, nígbà tí Shettima gba oyè “Enyi Ndigbo” èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ènìyàn ẹ̀yà Igbo.
Lára àwọn tí ó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú ààrẹ ní Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo, Hope Uzodimma, Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òsèlú APC, Alhaji Abdullahi Ganduje, Alága àti olùdarí Atlas Oranto Petroleum, Ọmọba Arthur Eze àti àwọn ènìyàn pàtàkì míràn.