Take a fresh look at your lifestyle.

Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra Nawọ́ Ìtọrẹ Àánú Sí Ilé Ìtọ́jú Àwọn Ọmọ Òrukàn

154

Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Arábìnrin Nonye Soludo ti pín Oúnjẹ, Owó àti àwọn ohun èlò míràn sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ orùkan tí ó wà ní ìpínlẹ̀ náà. Ó wá pàrọwà sí ọmọ Nàìjíríà láti máa fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn aláìní ní àwùjọ wa

 

Ó pe ìpè náà ní ìlú Onitsha nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn ní ìpínlẹ̀ náà ní ìgbáradì fún ọdún tuntun

 

Arábìnrin Soludo sàlàyé pé àbẹ̀wò náà wà lára ẹ̀kọ́ tí ọdún kérésìmesì múwá èyí tí ó jẹ́ àkókò àánú, ìfẹ́ àti ìrànlọ́wọ́ ọmọnìyàn

 

Comments are closed.

button