Ìgbìmọ̀ Ilé Asòfin lóri ọ̀rọ̀ Ọlọ́pàá ti rọ Mínísítà Fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́pàá àti ọ̀gá àgbà àpapọ̀ Àjọ Ọlọ́pàá láti gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ láti ríi dájú pé ètò àbò tí ó péye wà jákè-jádò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìgbìmọ̀ náà tí Sẹ́nétọ̀ Abdulhamid àti ọnọrébù Abubakar Yalleman jẹ́ alága fún sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí àwọn adari àjọ ọlọpaa naa fi arahàn níwájú igbimọ lati salaye lori eto isuna ti ọdun 2024
Ìgbìmọ̀ náà sọ pe dídáàbòbò ẹ̀mi àti dúkìá ará ìlú se pataki, nitori naa ni o se se pàtàkì fun ajọ ọlọpa lati má se kùnà ninu ojúse rẹ̀