Awuye-wuye Ìpínlẹ̀ Rivers Ń Tẹ̀síwájú Èyí Tí Ó Mú Kí Àwọn Kọmísọ́nà Kọ̀wé Fipò Sílẹ̀
Kọmísọ́nà Fún Ètò Ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Rivers, Ọ̀jọ̀gbọ́n Prince Mmom ti darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ méjì tí wọ́n kọ̀wé fipò sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers
Mmom síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìwé tí ó kọ ráńsẹ́ sí ọ́ọ́fìsì akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers àti ọ́ọ́fìsì gómìnà ní Ọjọ́bọ̀, ní ìlú Port Harcourt
Nínú ìwe tí ó kọ ráńsẹ́, ó sàpèjúwe fífi ipò sílẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wá láti inú òun. Lára àwọn tí ó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ síwájú rẹ̀ ní kọmísọ́nà fún ètò ìdájọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Zaccheaus Adangor, Ọ̀mọ̀wé Des George-kelly tí ó jẹ́ kọmísọ́nà fún iṣẹ́ òde, Emeka Woke tí ó wà fún àkànse iṣẹ́ àti Inime Aguma tí ó wà fún ìgbáyégbádùn ará ìlú.