Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Benue Pàṣẹ Títúléká Ní Àwọn Ìjọba Ìbílẹ̀- Agbẹnusọ Gómìnà
Ìjọba ìpínlẹ̀ Benue ti sàlàyé pé títú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ká tí ó wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin, lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò tí ó wáyé láti ọwọ́ àwọn ọmọ Asofin Ìpínlẹ̀ náà
Sir Tersoo Kula, tí ó jẹ́ olùfọ̀rọ̀léde fún Gómìnà Hyacinth Alia ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Àìkú, ní ìlú Makurdi
Kula sàlàyé pé, ìròyín òfegé ní èyí tí ó gbòde wípé Gómìnà Hyacinth Alia ni ó tú àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n dìbò yàn ká, sùgbọ́n ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọ asòfin ni ó pàṣẹ kí wọ́n lọ rọ ọ́ kún nílé lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn wọ́n
Leave a Reply