Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fi Ìdí Ìjáwé Olúborí Kefas Múlẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Gómìnà Tí Wọ́n Dìbòyàn Ní Ìpínlẹ̀ Taraba

0 181

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí ó wà ní ìlú Abuja ti fi ìdí ìjáwé olúborí Ọ̀mọ̀wé Kefas Agbu ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbo gómìnà tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹta

 

Gẹ́gẹ́ bí ìfẹnukò àwọn adájọ́ mẹ́ta tí ó se ìdájọ́ náà èyí tí adájọ́ Peter Affen darí, o ́fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé olùdíje sí ipò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú NNPP, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yahaya Sani àti ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀ tí ó pe ẹjọ́, kùnà láti sàfihàn ẹ̀sùn nínú ìwé ìfẹ̀hónúhàn wọn èyí tí ó pè fún fífagilé èsì ìdìbò tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹta

 

Ilé Ẹjọ́ sàpèjúwe ẹ̀sùn tí ẹgbẹ́ òsèlú NNPP fi kàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò rẹ́sẹ̀ walẹ̀, ó sì fi ìdí ìjáwé olúborí olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP múlẹ̀.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button