Ẹgbẹ́ Òsèlú APC ti fi ìdí ìgbáradì rẹ̀ múlẹ̀ fún ìwọ́de ìta-gbangba tí ó wáyé ní ìlú Kano ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òsèlú NNPP lòdì sí ìgbésẹ̀ náà
Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC se àgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀sùn tí ẹgbẹ́ alátakò fi léde, sùgbọ́n wọ́n fi ẹnu kò wípé, ìwóde náà le è wáyé ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ láìní sí wàhálà kankan
Wọ́n sàpèjúwe ìlú Kano gẹgẹ bi eyi ti o fi àyè gba alaafia ati ìdókoòwò lábẹ́ àkóso ẹgbẹ́ òsèlú APC tẹ́lẹ̀rí, wọ́n wá sàpèjúwe ẹ̀sùn ẹgbẹ́ òsèlú NNPP gẹgẹ bi eyi ti ko rẹśẹ̀ walẹ̀
Leave a Reply