Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn: Àjọ Ọlọ́pàá Pèpè Fún Àlàáfíà Àti Ìfọ̀kànbalẹ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa
Àjọ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Nasarawa ti se ìkìlọ̀ fún àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òsèlú láti jìnà sí ìwà tí ó le è da omi àlàáfíà ìlú rú síwájú ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà
Adelé Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ náà Shettima Muhammed ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Lafia, olú ìlú ìpínlẹ Nasarawa
Ó tẹ̀síwájú pé ààbò tí ó péye yóò wáyé síwájú ìdájọ́ ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn láàrin Gomina Abdullahi Sule àti olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP nínú ìdìbò sí ipò gómìnà ọdún 2023.
Leave a Reply