Olùdámọ̀ràn fún ètò ààbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mallam Nuhu Ribadu, tí ro àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ (NLC) àtí (TUC) látí Fágilè ìdá-ìṣẹ́-sílẹ̀ wọ́n káàkiri Orílẹ̀-èdè lásìkò tó tún bú ẹnú atẹ́ lú ikọlù Ààrẹ ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ NLC, Comrade Joe Ajaero.
Nínú àtẹ̀jáde kàn tí Zakari U. Mijinyawa, Olórí ètò ìròyìn tí Ilé-iṣẹ́ (ONSA) naa, to ṣàlàyé ìbẹrù Àjọ NSA náà lórí ipò tí ètò ọrọ̀ ajé Orílẹ̀-èdè náà wà èyí tí iyanṣẹlodi náà lè mú ìpalára bá àwọn aráàlú àti àwọn oún mìíràn.
Do Not Localize The Truth – Nigeria Workers President is a National and Global Personality, We demand for Justice Now!!! pic.twitter.com/EGRN5tXnN4
— Nigeria Labour Congress HQ (@NLCHeadquarters) November 14, 2023
Gẹ́gẹ́ bí NSA ṣé wí, díẹ̀ nínú àwọn afurasi náà ní ọwọ́ tí bá, tí ìwádìí sí ń lọ́ lọwọ́ lórí ikọlù náà.

Nibayii, Minisita fún ètò Ìròyìn àti Àlàyé tí Orílẹ̀-èdè yí, Mallam Mohammed Idris Malagi, tún tí ráwọ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn alákóso àjọ Òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, pé kí wọ́n ṣàfihàn ọmọ Orílẹ̀-èdè réré, kí wọ́n sì ronú lórí ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀-ajé Orílẹ̀-èdè yìí.
Tí àbá rántí, láìpẹ́ yìí ní àwọn kàn kọlù Ààrẹ ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ NLC ní ọjọ́ kínní oṣù kọkànlá ní ìpínlẹ̀ Imo, làkókò ìwọ́de kàn káàkiri ìpínlẹ̀ náà.
STRIKE ACTION COMMENCES MIDNIGHT TODAY pic.twitter.com/RdHQbr3LX9
— Nigeria Labour Congress HQ (@NLCHeadquarters) November 13, 2023
Làkókò tó ń kéde ìdá-ìṣẹ́-sílẹ̀ náà ní Ìpínlẹ̀ Imo, Ọ̀gbẹ́ni Ajaero sọ pé ìgbésẹ Àjọ Òṣìṣẹ́ náà jẹ́ àtakò látí lòdì sí “irúfin Òṣìṣẹ́ àtí ìtẹ ẹtọ ọmọnìyàn lójú mọlé ní Ìpínlẹ̀.
Leave a Reply