Orílẹ̀-èdè Russia ti pé akiyesi pé
ìkọ̀lù Ísraẹ́lì sí Gaza Strip Leè ta kọjá ibi ti wọn kò lérò bí orílẹ̀-èdè Ísraẹ́lì se n gbáradì fún ìkọ̀lù láti ori ilẹ̀
Ní Gaza ti wọ́n dógò tì, oye àwọn elétò irànwọ́ ti lọlẹ̀, olùgbé n sìn òkú sínú ibi ìsìnkú àpapọ̀ sí, bi oye àwọn òkú ti wọn kìí se ológun se n lọ sókè lálá.
Ààrẹ Russia, Vladimir Putin ti ṣe ìkìlọ̀ pé ìkọ̀lù náà leè ta koja àárín gbùngbùn ìlà oòrùn, o tún sọ pé, kò tọ̀na pé kí àwọn aláìmọwọ́ mọsẹ̀ obinrin, ògo wẹẹre àti àgbà ni Gaza máa jẹ ìyà ti wọn kò mọ̀dí nítorí àṣìṣe àwọn kan.
Bí òkú àwọn ènìyàn se n lọ sókè ni Gaza, àwọn ará Palestine n sìn òkú ti wọn kò mọ ẹyẹ tó su wọ́n sínú kòtò ìsìnkú àpapọ̀, pẹ̀lú nọ́ḿbà sùgbọ́n tó yẹ kó jẹ́ orúkọ, olùgbé kan sọ èyí.
Ìkọ̀lù Israẹli ti dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni ègbodò, Mínísíirì elétò ìlera ni Gaza sọ èyí ní ọjọ́ Ọjọ́rú..
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply