Adèyìnmú Agbabọ́ọ̀lù Liverpool Andy Roberson ti ṣe iṣẹ́ abẹ èjìká látàrí ìfarapa tó ní nígbà ti ikọ̀ rẹ̀ ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Scotland
Ọ̀gbẹ́ni Robertson ní ìfarapa náà nígbà tó kọlu asólé ilẹ̀ Spain ni ibi ìdíje Ìperegedé Euro 2024 ni oṣù kẹwàá.
Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ikọ̀ Liverpool, Jurgen Klopp ko leè sọ ìgbà ati àkókò tí yóò padà sí ori papa fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
“Robbo ti ṣe iṣẹ́ abẹ àseyorí, ara yiyá rẹ̀ di ìgbà tí ó bá ti jí , ” Klopp sọ èyí ni ọjọ́ Ọjọ́rú.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply