Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀-èdè yi ti fún òun ni agbára láti sìn Nàìjíríà láì fi ti ẹlẹ́yàmẹyà, òṣèlú tàbí ẹ̀sìn se, ó tún ran òun lọ́wọ́ láti ri pé gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tú bọ̀ wà ní ìṣọ̀kan.
Ààrẹ Tinubu ṣọ eyi nínú àkọsílẹ̀ kan to buwọ́lù ti àkòrí rẹ̀ jẹ́ : ÀKÓKÒ NÌYÍ LÁTI KỌ́ ORÍLẸ̀-ÈDÈ WA PAPỌ̀.
Lórí ẹjọ́ ko-te-mi-lorun ti Oludije ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àtí Labour Party, Ọ̀gbẹ́ni Atiku àti Peter Obi lórí ti ifáfitì Chicago ti ààrẹ lọ, ẹ̀sùn lórí pé àjọ INEC kò gbé ètò ikede èsì ìdìbò jáde lórí ẹ̀rọ Mọ́hùnmáwòrán tàbí àtẹ IReV bó se ń lọ lọwọ́, lórí ọ̀rọ̀ nípa ògun egbogi olóró ti won niTinubu ti pàdánù oye owó tó tó eẹ̀ẹ́degbẹ̀ta Dọ́la ati yíyan igbákejì ààrẹ Kashim Shetima ni ìgbà méjì tí ọ̀gbẹ́ni Peter Obi kọ sita, ilé ẹjọ tó ga jùlọ ní orílẹ̀-èdè yìí sọ pé gbogbo àwọn ẹsùn náà ko lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply