Àjọ Tí Ó Ń Pèsè Iná Mọ̀nàmọ́ná Ti Parí Ètò Láti Mú Iná Dé Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àyè Ní ọdún 2024
Àjọ tí ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún ìgbèríko ti parí ètò láti mú iná dé gbogbo àyè tí ó yẹ pẹ̀lú àwọn àlàkalẹ ètò tí yóò mú kí isẹ́ náà kẹ́ṣẹ járí.
Alákòóso fún ètò náà, Mutari Ibrahim ni ó kéde ọ̀rọ̀ náà níbi ìfiléde kan tí ó wáyé ní ìlú Abuja.
Ó tẹ̀síwájú pé àjọ náà ti setán láti fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti pèsè iná mònàmọ́ná tí ó múná-dóko fún mùtú-mùwà.
Leave a Reply