Mínísítà fún Ọrọ ilẹ̀ Òkèèrè, Yusuf Tuggar sọ pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí n rí ànfààní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Belt and Road Initiative BRI bí àwọn Orílẹ̀-èdè Àgbáyé ṣé kópa nínú tí ọdún 2023 ní Orílẹ̀-èdè China.
O sọ̀rọ̀ yìí nínú ifọrọwanilẹnuwo pẹ̀lú akọroyin Voice of Nigeria ní Ìlú Beijing, níbí tó tí tẹnu mọ́ pàtàkì àpéjọ náà, èyí tó so àwọn Orílẹ̀-èdè Àgbáyé pọ̀.
Lórí báwo ní Nàìjíríà ṣé lé jé ànfààní láti inú àpéjọ náà, Mínísítà náà sọ pé Orílẹ̀-èdè tí n ṣé ìkórè púpọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ BRI, pàápàá ní àwọn agbègbè òun èlò amayedẹrun.
Mínísítà náà tẹnu mọ́ pé Nàìjíríà tún n kojú ìṣòro àìníṣẹ́ nípasẹ àwọn iṣẹ́ amayedẹrun tí a n ṣé ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà.
Leave a Reply