Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Yóò Sìn Nàìjíríà Dé Ilẹ̀ Ìlérí – VP Shettima

0 274

Ìgbákejì Ààrẹ Orílè-èdè Nàìjíríà, Kashim Shettima tí fí ìrètí rẹ̀ hàn pé Nàìjíríà yóò bóri àwọn ìṣòro tó ń kojú rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́.

O ṣé ìkéde náà ní Beijing, China, ní ọjọ́ Ajé làkókò ìpàdé pẹ̀lú Aṣojú àti àwọn òṣìṣẹ́ tí Ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tí Nàìjíríà ní Ìlú China.

VP Shettima, tó wa ní Orílẹ̀-èdè China láti ṣé aṣojú Ààrẹ Bola Tinubu níbí ìpàdé ẹlẹẹkẹta ‘3rd Belt and Road Initiative,’ èyí tí Orílẹ̀-èdè China gbá àlejò rẹ̀, Ó ṣé àkíyèsí pé àwọn Adari Nàìjíríà ní àwọn ìmọ oyè gẹ́gẹ́ bí olórí tó tayọ ti a lè lò fún àpẹẹrẹ.

VP Shettima ṣàfikún pé “gbogbo òun tí a nilo ní láti ṣé àtìlẹ́yìn fún Ààrẹ Tinubu.”

Nígbàtí o n sọ̀rọ̀, aṣojú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí China, Ahmad Jedda, sọ pé àbẹwò tí Ìgbákejì Ààrẹ sí China yóò ṣé ìrànlọ́wọ́ láti mú kí àsopọ Nàìjíríà àti China pọ̀ sí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button