Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Se Ìpàdé Pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Benue Àti Nasarawa

0 186

 

Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue, Hyacinth Alia
bá ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe Ìpàdé pọ̀, o bèrè fún atìlẹ́yìn láti kó àwọn ogúnléndé ìpínlẹ̀ náà kúrò lọ sí ibòmíràn.

Ó tun bere lọwọ ìjọba lati gbe igbèsè owó irinwó bílíọ̀nù Naira ti ipinlẹ náà jẹ tí wọn jogún lọ sílẹ̀.

Ó wa dupẹ lọwọ ìjọba fún owó ìrànwọ́ ti ìjọba fún wọn látàrí imukuro owó orí epo, wí pé ó ti jẹ́ ki ìtura bá àwọn ènìyàn.

Ọ̀gbẹ́ni Alia fi kun pe, ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ ti jẹ́ ki àwọn náà se bẹbẹ nípa ìpèsè oúnjẹ yanturu.
“O jẹ́ kó yá wa lórí láti sa gbogbo ipá wa nipa ìpèsè oúnjẹ”

Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue jẹ́ kò di mímọ̀ pé, àlàáfíà ti jọba ni ìpínlẹ̀ náà, eléyìí sí fún àwọn àgbẹ̀ láti padà lọ sí oko láti lọ dá oko.

Nigba ti o n ba àwọn oníròyìn sọrọ n tirẹ ni gbọ̀ngàn ààrẹ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa, Abdullahi Sule, sọ pé ipò ti àwọn eniyan mẹrin ti wọn jẹ akékọ̀ọ́ ifáfitì ìpínlẹ̀ Nasarawa ti wọn jígbé lọ wà lọ́kàn ààrẹ, o je ko di mímọ pe ologun se gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà láti ri pe wọ́n rí wọn gba padà ni àná láì gba nǹkan kan lọ́wọ́ wọn, ó dupẹ lọwọ ààrẹ.

Gómìnà Sule fi lede pe ààrẹ ni inú dídùn láti dá ilé ìṣẹ́ tuntun tó n pèsè ohun èèlò
Lithium ni ìpínlẹ̀ náà. Tí ó bá yọrí si rere tán, yóò máa pèsè Tọ́ọ̀nù igba lọ́nà Àádọ̀rún (18,000 tonnes)

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button