Bendel Insurance FC tí ìlú Benin gbá omí lójú Shooting Stars Sports Club (3SC) tí ìlú Ibadan 2-0 nínú ifẹsẹwọnsẹ ọsẹ Kejì nínú ìdíje Nigeria Professional Football League 2023/2024 (NPFL).
Ìkọ Insurance mí àwọ̀n ní iṣẹju kẹjọ tí ifẹsẹwọnsẹ náà bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ àgbábọ́ọ̀lù 3SC Garli Falke ní pápá ìṣèré Samuel Ogbemudia ní Benin.
Gbogbo akitiyan ìkọ 3SC láti dá pàdà ló já sí pàbó bí ìkọ agbábọ́ọ̀lù Insurance ṣé bóri ìdajì àkọ́kọ́ nínú ifẹsẹwọnsẹ náà.
Ní ìdá Kejì, Bendel Insurance ló ọgbọn atinuda ní iṣẹju Kejì-lè-làádọ́rin bí o ṣé rọpo agbabọọlu Jude Ebhohon pẹ̀lú Vincent Augustus, Paul Obatan pẹ̀lú Austin Ogunye, àti Akpos Godness pẹ̀lú Evans Ogbonda.
Ìgbésẹ̀ náà yọrí sí réré bí Ogbonda ṣé fí bọ́ọ̀lù ránṣẹ sí Stanley Okorom èyí tó gbá wọlé fún ìkọ rẹ̀ ní iṣẹju Kejì-dín-lọgọrin.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìkọ méjèèjì tí má ń ṣé fà ń fà láàrin ará wọ́n nínú ìdíje NPFL.
Leave a Reply