Ìkọ̀lù Orílẹ̀-èdè Russia nípa lílo “drone” àti ohun ìjà olóró ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì tí gba ẹ̀mí ọmọdékùnrin ẹni Odyun Mẹ̀wá ni agbègbè Àríwá ìlà Oòrùn ìlú Kharkiv, ó tún ba nǹkan jíje oníkóró àti ohun èèlò ibi ti ọkọ̀ ojú omi ti ń jáde tàbí gúnlẹ̀ sí jẹ́. Ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè Ukraine sọ èyí.
Ikọlu náà ló tẹ̀lé ìkọ̀lù ti Russia se ni ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ti òṣìṣẹ́ ilé Ukraine sọ pé ọkàn le laadota- ènìyàn ló gbẹ̀mí mì ni Àríwá- ìlà oòrùn Ukraine nígbà ti wọ́n n péjọpọ̀ láti dárò ológun kan tó papòdà.
Nínú Ikọlu tó ṣẹṣẹ wáyé, Ikọlu láti inú òfurufú láti ọwọ́ ile Ukraine já ọkọ̀ òfurufú drone ti Russia mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ninu mẹ́tàlélọ́gbọ̀n bọ́ lulè láti annexed Crimea peninsular, ọmọ ológun òfurufú sọ èyí.
Ni Ikọlu ọ̀tọ̀ sí ilu Kharkiv, ènìyàn mẹ́ìndínlógún lo farapa pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́wàá ti wọn pa, Gómìnà elekajeka, Oleh Synehubov
lọ sí èyí.
Ọmọ kékeré jojolo ọmọ oṣù Mokanla wà lára àwọn tí farapa, ile ati ọkọ di bibajẹ, gbogbo èyí ló sọ.
Moscow sọ pé àwọn kò mọ̀ọ́mọ̀ dojuko ènìyàn ti kii se ológun, sugbon ọ̀pọ̀ eniyan ti gbẹ̀mì mì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan sí ti sí bíbàjẹ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply