Take a fresh look at your lifestyle.

Somaliland Kọ́ Ìgbésẹ Museveni Látí Yànjú Ọrọ̀ Ìṣọ́kàn

0 229

Agbégbé Somaliland tó yá sọ̀tọ̀ lárá Orílẹ̀-èdè Somalia sọ pé àwọn kó ní eró láti jíróró ìṣọ́kàn pẹ̀lú Somalia, bí wọ́n ṣé kọ́ àbá Ààrẹ Uganda Yoweri Museveni látí ṣé ìjítóró ìṣọ́kàn làárin wọ́n.

Alaye kan ti ile-iṣẹ ti ilẹ okeere ti Somaliland sọ pe Hargeysa yoo gba lati ṣe ijiroro pẹlu Mogadishu nikan to ba jẹ lori ero ọjọ iwaju ipinlẹ mejeeji lọtọtọ.

Ijọba Somaliland kede ominira lati Somalia ni ọdun 1991 ṣugbọn ko ti gba idanimọ agbaye fun ominira.

Arẹ Museveni sọ erongba rẹ lakoko ti aṣoju ti Aare Somaliland ṣe abẹwo si Uganda.

O sọ pe iyapa ti Somaliland ko fi aye gba igbiyanju lati kọ orilẹ-ede Somalia to lagbara, to si ni ilọsiwaju.
Orile-ede Somaliland ti n ba awọn ọmọ ogun ipinya funra rẹ sọrọ,

ija nla ti waye laarin awọn ọmọ ogun Somaliland ati awọn ọmọ ogun agbegbe kan latidaduro ni ayika ilu Las Anod ni oṣu Kínní.

Awọn ọmọ ogun yii n wa lati yapa kuro ni Somaliland lati ṣẹda ipinlẹ tiwọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button