Gbájúgbájà agbágbọ̀ọ́lù ẹlẹ́yìn lóri tàbíìlì tó gá júlọ ní Áfíríkà, Aruna Quadri, sún sóke lóri tàbíìlì ìwọ̀n látí ìkéjidìnlógun sí ìkẹ́rindìnlógun lágbáyé fún àwọn ọkunrin.
Eyi wa lẹyin to ṣe aṣeyọri rẹ ninu idije “ITTF Africa Senior Championships” ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ bo ṣe bori Ahmed Saleh ti Egypt ni ipari idije awọn ọkunrin ni Tunisia ni ọjọ Aiku to kọja.
Ọmọ orilẹ-ede Naijiria naa gba ife naa pẹlu ami ayo mẹrin si 4-0 (11-2, 12-10, 11-6, 11-6) bo ṣe peregede lati kopa ninu idije Olimpiiki “Paris 2024.”
Leave a Reply