Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ti àwọn gbọgán àti ibi ìgbafẹ́ mẹ́jọ pa nitori ààbò pípé, láàrin Ikeja, Victoria Island ni àwọn ìṣẹlẹ̀ náà ti wáyé.
Adarí àgbà pátápátá fún ilẹ iṣé ààbò ni ìpínlẹ̀ Eko, Ọ̀gbẹ́ni Lanre Mojola lo sọ èyí di mímọ̀, Ó ni èyí wáyé nítorí pé kì ààbò tó dájú ba le wa nínú ìlú.
Mojola sọ di mímọ̀ wí pé àwọn n gbìyànjú láti rí wí, ìjàmbá ọkọ̀ di ohun ìgbàgbé àti wí pé dúkìá àti èmí àwon ènìyàn wa ni àlàáfíà.
Ó ṣe àpèjúwe ètò náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí o ba òfin mú, o ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìgbafẹ́ yìí ni o n ṣe ohun ti o lòdì sí òfin tí o sí n ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn láwùjọ
Mojola ni àwọn ko ni sinmi láti rí wí pé ìwà ìbàjẹ́ di ohun ẹtì, àti wí pé àwọn yóò gbìyànjú láti mú àlàáfíà àti ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Eko.

Leave a Reply