Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí Ọba Igbinedion ti ilé Benin kú órire ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Ọ̀kàndínláàdọ́rún èyí tí o ń ṣe lóni.
Ó ṣe àpèjúwe ọlọ́jọ́ìbí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe gudugudu méje láàrin ìlú àti ìdàgbàsókè ń lá fún ètò ọ̀rọ̀ ajé.
Nínú atẹjade èyí tí olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ayélujára, olóyè Ajuri Ngelele bù wọ lu, Ààrẹ Gbóríyìn fún ọlọ́jọ́ìbí fún àwọn ipá takuntakun ti o kó fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó sí gbàdúrà fún èmí fún èmí gígùn àti àlàáfíà.
Leave a Reply