Take a fresh look at your lifestyle.

Irin Gbígbé: Olùdíje Ọmọ Nàìjíríà Mẹ́fà Yóò Sojú Fún Wa Ní Ìdíje Àgbáyé

0 328

 

Olùdíje Mẹfa ni yóò sojú fún Nàìjíríà ní ibi Ìdíje Irin gbígbé àgbáyé International Weightlifting Federation (IWF) World Championship ní ọ̀ṣẹ̀ yìí ni Riyadh, orílẹ̀-èdè Saudi Arabia, òṣìṣẹ́ kan sọ èyí.

Olórí akọ́ni irin gbígbé fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ojadi Aduche sọ pé ìdíje náà yóò jẹ́ ti Ìperegedé fún ti 2024 Summer Olympics ti yóò wáyé ni Paris, orílẹ̀-èdè Faransé.

Ó sọ pé àwọn agbérin náà jẹ́ obìnrin mẹ́rin àti ọkùnrin méjì, orúkọ wọn ni Adijat Olarinoye (59kg), Rofiat Lawal (59kg), Joy Eze (71kg) Ruth Ogbeifo (64 kg) Umoafia Edidiong (67kg) ati Desmond Akanlo (89kg).

Ó sọ pé àwọn Olùdíje agbérin náà ti wà ní ìpàgọ́ níbi tí wọ́n ti ń gbáradì fún bí ọ̀ṣẹ̀ márùn ún báyìí àti pé ìrètí wà pé wọn yóò se dáradára nínú ìdíje náà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button