Bukayo Saka ti ikọ̀ Arsenal ni wotn ti dárúkọ gẹ́gẹ́ bí agbáboolu tó dára jù fún ikọ̀ England ni ọdún Kejì ni sísẹ̀ntẹ̀lé, àjọ English Football Association ló kéde rẹ̀.
Bí Saka se se bẹbẹ ni sáà ìgbá bọ́lù ọdún 2022/2023 lọ fún ni àmì ẹ̀yẹ yí, ti àwọn èniyàn sí dìbò fún. Won dibo fún
bi agbaboolu tó fako yọ jù láàrin àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ bíi Jude Bellingham àti striker Harry tí wọn se ipò keji àti ìkẹ́ta ní àpapọ̀.
Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ England ni oṣù Kẹ́wàá ọdún 2020 nígbà tí o si gbá ayò mejte wọlé nínú ìkópa mẹ́wàá tí ayò mẹ́ta tó gbá wọlé níbi ìdíje Ife àgbáyé ti ọdún 2022 sí wà lára wọn.
Wọ́n dárúkọ rẹ̀ bí agbábọ́ọ̀lù tó yanrantí jùlọ níbi ìsíde ìdíje ikọ̀ England pẹ̀lú Iran ní ìlú Qatar ti wọn sì borí pẹlú ayò mẹ́fà sí méjì (6-2), bákannáà wọ́n borí ikọ̀ Ukraine àti North Macedonia ní ti ìdíje Ìperegedé Euro 2024, ayò ìkẹyìn yìí ni ó ti gbá bọ́ọ̀lù oníbẹta wọlé.
Wọ́n tún dárúkọ rẹ̀ bí agbábọ́ọ̀lù ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ PFA ti Sáà yí ní ti Líígìì PFA Premier ti ọdún yìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply