Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu ti rọ àjọ àgbáyé láti túnbọ̀ se atilẹyin fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ki iṣé àwọn oníṣe láabi ba di ẹni ìgbàgbé.
Ààrẹ ni nípa báyìí àlàáfíà yóò joba àti ìdàgbàsókè ni gbogbo ọ̀nà, eleyii yóò sì mu kí iṣé ati ìpọ́jú parí ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nígbà tí Ààrẹ gba àlejò Ọ̀gbéni Vladimir Voronkv, to jẹ Akọ́wẹ́ àgbà fún ẹgbẹ́ náà ni ilé ìjọba ni Ọjọ́bọ̀, Ààrẹ ni ìwà ìbàjẹ́ ati janduku tí wá gbilẹ ti o sí n ṣe àkóbá nlá fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ rẹ, Mínísítà fún fún ọ̀rọ̀ òkè òkun Yusuf Maitama Tugher sọ wí pé òun ti ṣàlàyé àwọn ọ̀nà àbayọ sí ìdojúkọ náà láàrin àjọ àgbáyé láti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n Títí di òní kò sí ìdáhùn sí ìbéèrè òun.
Wọ́n ṣe ètò ati ni ìpàdé ní ìlú Abuja ní oṣù kẹrin ọdún 2024.
Leave a Reply