Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kẹ́dùn pẹlú ìjọba, àti àwọn ènìyàn orile-ede South Africa látàrí ìjàmbá Iná tó ṣẹlẹ̀ lára ilé ọlọ́pọ̀lọpọ̀ àjà ní ìlú Johannesburg níbí ti òkòwò ti fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Ìbánikẹ́dùn ààrẹ jẹyọ nínú àpilẹ̀kọ kan tí olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ìròyìn àti ìfiléde, Ajuri Ngelale buwọ́lù ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀.
Iná jó ilé alájá Márùn ún ní àárin gbùngbùn ilú Johannesburg, tó sì pa ènìyàn tó ju àádọ̀rin lọ, eléyìí ti àwọn ògo wẹẹrẹ wà lára wọn ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀..
Méjìléláàdọ̀ta ni ìròyìn rò pé wọ́n farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó burú jáì náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply