Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń tukọ̀ orílẹ̀-èdè yí lọ́wọ́, All Progressives Congress, APC ti kéde pé kí ọmọ ẹgbẹ́ Mẹ́rin dín lọ́gbọ̀n lọ rọ́kú nílé látàrí àgbèrè ẹgbẹ́ ṣíse.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí wọn se irú rẹ̀ fún ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ̀rin fún irú ẹ̀sùn kan náà ní ọjọ́ Ọjọ́rú.
Bí wọ́n ṣe lé wọn dànù wà ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti alága ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ osun, ọ̀gbẹ́ni Sooko Lawal buwọ́lù.
Àwọn ti wọ́n yọ bí ẹní yọ jìgá ni wọ̀nyí:
Alhaji Moshood Adeoti, Najeem Salami, Sẹ́nétọ̀. Mudasiru Hussain, Adelowo Adebiyi, ọ̀gbẹ́ni Adelani Baderinwa, ọ̀gbẹ́ni Sikiru Ayedun, Kazeem Salami, Alhaji Adesiji Azeez, Gbenga Akano.
Awọn yooku ni: ọ̀gbẹ́ni Kunle Ige, ọ̀gbẹ́ni Biodun Agboola, Gbenga Awosode, Rasheed Opatola, Gbenga Ogunkanmi, Israel Oyekunle, MBO Ibraheem, Akeem Olaoye, Francis Famurewa, ọ̀gbẹ́ni Tajudeen Famuyide.
Ìyáàfin Adenike Abioye, Wasiu Adebayo, Rasheed Afolabi, ọ̀gbẹ́ni Segun Olanibi, ọ̀gbẹ́ni Tunde Ajilore, ọ̀gbẹ́ni Ganiyu Ismaila Opeyemi, Zakariah Khalid-Olaoluwa-South LCDA.
Ni ọjọ Ojoru, alaga egbe kéde yiyọ ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ̀rin kúrò látàrí pé wọ́n ń gba iṣẹ́ tàbí ipò lábẹ́ ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply