Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Alátakò Gabon Pé Ológun Láti Ka Ìbò Tó Kù

0 266

 

Ìdìtẹ̀ gbàjọba ológun ní orílẹ̀-èdè Gabon fẹ́ jẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò máa ní ìrètí díẹ̀díẹ̀. Lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ológun tó dìtẹ̀gbàjọba látàrí pé wọ́n kò ní ìgbàgbọ nínú ìbò tó kọjá, olórí ẹgbẹ́ òṣèlú àlàtako pe àwọn ológun láti ka Ìbò tó kù nínú ìbò tó wáyé ní ọjọ Àbámẹ̀ta tó kọjá.

O gbagbo pe oun, Ondo Ossa lo jáwé Olubori ni wọ́n ba ka ibo to ku.

Ologun gba ijoba lowo oloselu leyin ti won ti kéde pé ogbeni Bongo lo jáwé olubori ninu ibo ààrẹ to koja, wọn ni ibo naa ni owo kan abosi ninu, eru ni.

Olùdíje Ossa ní ìdá ìbò 30.77 nínú ọgọ́rùn, ọ̀gbẹ́ni Bongo sí ni ìdá ibo 64.27
nínú ọgọ́rùn. Lẹ́yìn èyí, ológun fagile èsì ìbò, wọ́n sì sọ gbogbo agbára Ilé Isẹ́ gbogbo di asán.

Ní ọjọ́ Ojọ́bọ̀, wọ́n kéde pé, ọ̀gágun Brice Oligui Nguema ni won yóò búra fún gẹ́gẹ́ bi ààrẹ ìgbé-jọba padà fún alágbádá láì mọ bí yóò ṣẹ pẹ́ sí.

Ọ̀gbẹ́ni Ossa náà ti pe àwọn ológun láti jọ jíròrò pọ̀ ní ọ̀nà tó ni ifẹ sí orílẹ̀-èdè wọn nítorí àwọn ni ó mọ ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro orílẹ̀-èdè wọn, orílẹ̀-èdè won yóò sì jáde takọtakọ

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button