Take a fresh look at your lifestyle.

Àkókò Ìparí Tuntun Eré Bọ́ọ̀lù Òsì Ni- Òṣìṣẹ́ Àjọ UEFA

0 365

Olóyè pàtàkì nínú eré bọ́ọ̀lù àjọ ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì Zvonimir Boban, ti sọ pé àkókò ìdáré dúró tuntun ti eré bọ́ọ̀lù aláwọ̀ funfun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde láti máṣe fàyè fún ìfàsìkò ṣòfò kò dára rárá,” ìwà òmùgọ̀ gbáà ni”, wọ́n kò sì ní lòó fún eré ìdíje UEFA.

Àjọ afunfèrè ilẹ̀ England sọ pé, ó túmọ̀ sì pé, olùṣàkóso eré bọ́ọ̀lù náà yóò fi àsìkò kún un látàrí àjoyọ̀ bọ́ọ̀lù ti wọn gbá wọlé, pàsípàrọ̀ agbábọ́ọ̀lù àti àkókò ìfarapa. Ọnà láti fi kún àkókò eré ìdárayá náà ni èyí, ti akókò yóò sì kọja ọgọ́rùn ún ìsẹ́jú.

Ògbóìtarìgì agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Manchester City ní ipò àárín, Kevin De Bruyne, adi ẹ̀yìn mú agbábọ́ọ̀lù fún Manchester United, Raphael Varane àti ọ̀pọ̀ agbábọ́ọ̀lù union FIFPRO ti tako ìlànà ọ̀tun náà pé yóò máa mú kí iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù pọ̀ si.

“Ki wọ́n máa fi ìsẹ́jú méjìlá, mẹ́tàlá, mẹ́rinlá kún eré ìdíje bọ́ọ̀lù, ìwà òmùgọ̀ àti nǹkan burúkú gbáà ni”, agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ ikọ̀ AC Milan àti Croatia ni ipò àárín, Boban ló sọ bẹ́ẹ̀
.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button