Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Oyo Rọ Gómìnà Láti Tú Ọ̀nà Se

0 187

 

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Oyo níbi ìjókòó wọn ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ti rọ Gómìnà Seyi Makinde láti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni ìjọba ìbílẹ̀ Ogooluwa àti Surulere ìpínlẹ̀ náà ni kíámọ́sá.

Ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ tó sojú fún ìpín Surulere Ogooluwa, Onarebu Abideen Ogundare sọ pé ipò tí àwọn ọ̀nà náà wà báyìí burú jáì, wọ́n sì nílò àtúnṣe ní kíámọ́sá kí àwọn ènìyàn le ráyè jẹ mùdùnmúndùn ìjọba àwarawa.

O sọ pé ọnà náà sọ ọpọlọpọ igberiko papo to n lowo ninu Ise Oko ogbin orísìí nnkán ati ọsin eranko abiyẹ́ ni orile-ede Naijiria, fún àpẹrẹ oko Amo to je ilumoka.

Amòfin náà sọ pé àìsí ọ̀nà tí kò dára ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ okòwò ní ipinlẹ náà dénú lẹ̀, kò sí jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ dá iṣẹ́ sílẹ̀ wá.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wà rọ ìjọba láti tètè se ọ̀nà tó já geere lọ sí Iresaapa-Iresaadu Phase 2, Mowolowo-Iwo Ate Phase 1 àti Ipeba lọ si Ajaawa kí àwọn ènìyàn agbègbè náà le jẹ ànfàní eto “Omituntun 2.0 ” ti ìjọba gbékalẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button