Take a fresh look at your lifestyle.

Kòsí Ààyè Fún Ọkọ̀ Òfúrufú Láti Fò Lo Sí Málì Àti Burkina Faso

0 255

 

Àjọ tó ń rí sì fífò ọkọ̀ ofurufu ti orílè-èdè Faransé ti fi òfin de fífò lọ bibọ̀ ọkọ̀ Òfúrufú lọ si Bamako àti Ouagadougou títí di ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹjọ látàrí ìdìitẹ̀gbàjoba tó wáyé ni orílẹ̀-èdè Niger nítorí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti òṣèlú ni agbègbè náà, aláṣẹ ètò òfúrufú sọ èyí ní ọjọ́ Ẹtì.

 

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Málì àti Burkina Faso fọwọ́ sí ìdìitẹ̀gbàjọ̀ba tó wáyé ni Niger ni ọjọ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje.

 

Àjọ ECOWAS ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ se ìkìlọ̀ pé àwọn ń bọ̀ wa gba ìjọba padà fún ààrẹ Mohamed Bazoum ti wọ́n yọ bi ẹni yọ jìgá láti ọwọ́ àwọn ológun ilẹ̀ náà.

 

Títì pa ti wọ́n ti òfúrufú ilẹ̀ Niger jẹ́ ki ilé ìṣẹ́ máa lo ọ̀pọ̀lopọ̀ àsìkò kí wọ́n tó dé òkè òkun, iye àsìkò ìrìnà náà sì pọ̀ sí.

 

Àjọ tó ń rí sì fífò ọkọ̀ ofurufu ti orílè-èdè Faransé sọ pé àlàáfíà àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ Òfúrufú àti àwọn oníbárà wọn ló jẹ wọ́n lógún.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button