Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ti sọ pé òun fọwọ́ sí ètò ‘Heritage Voyage of Return’ tí o wà fún ìparapọ̀ gbogbo ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ láti ìran wọn padà wá sí Orisun wọn.
Ó sọ pe ètò náà jẹ́ kí wọ́n mọ ìtàn bi wọ́n se sẹ̀ wá àti ọdún tó ti pẹ́, yóò sì tún mú kí ọrọ̀ ajé ilẹ̀ adúláwọ̀ bú rẹ́kẹ́
Ààrẹ sọ èyí nígbà tó gba àlejò láti ọ̀dọ̀ ẹni ti wọ́n fi àmì ẹ̀yẹ ‘Nobel’ dá lọ́lá nì – ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Soyinka pẹ̀lú àwọn olùdásílẹ̀ ètò náà ní ọjọ́ Ẹtì ní Abuja.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply