Take a fresh look at your lifestyle.

Super Falcons Peregede Sí Ìpélé Òní Ìkọ Mẹ́rìndínlógún Níbí Ìfé Àgbáyé Àwọn Obìnrin

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 371

Super Falcons ti Nàìjíríà tí yégé sí ìpélé òní ìkọ mẹ́rìndìlogùn nínú ìdíje Àgbáyé tí àwọn Obìnrin ‘FIFA Women’s World Cup’ tí ọdún 2023 fún ìgbà kẹta lẹyìn tí wọ́n tá 0-0 pẹ̀lú ìkọ Republic of Ireland ní ọjọ́ Ajé.


Ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ tó gbóná ní pápá iṣere Brisbane tí Australia bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí ìkọ Ireland ṣé jẹ́ gábá ní kété tí ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ náà bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìkọ Nàìjíríà kojú wọ́n pẹ̀lú akin bí ọmọ ilẹ Nàìjíríà Asisat Oshoala ṣé pàdánù ànfààní tó dára kàn nígbàtí Louise Quinn fún ní bọ́ọ̀lù lásìkò tí wọ́n wálé lọrùn.

Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú ìkọ Nàìjíríà, wọ́n kò rí bọ́ọ̀lù gbà sí àwọ̀n títí tí ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ náà fí wá sí ìpamọ ṣùgbọ́n wọ́n tí peregede sí ìpélé tó kàn bí wọ́n ṣé wà ní ipò Kejì lórí tábìlì.

Tún kà nípa:Bí Eré Bí Eré, Super Falcon Dásọ Ìyà Fún Ẹgbẹ́ Agbábọ̀ọ̀lù Australia Pẹ̀lú Àmì Ayò Mẹ́ta Sí Méjì

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Australia ló máà kópa ninu ìpele ẹ́lẹni mẹ́rìndìnlogun 16 látí inú Group B pẹ̀lú bí Australia ṣé jáwé jókòó jẹ̀ fún Canada pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rìn sí odò.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn oludije tí Group B, Nàìjíríà yóò kojú àwọn olubori ní Group D ní ìpele 16 ní ọjọ́ keje, Oṣù Kẹjọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button