Ilé-iṣẹ́ ààbò tí Japan sọ pé òún tí ríi àwọn ọkọ ogún ojú-omí Russia méjì nínú omí nítòsí Taiwan àtí erékùṣù Okinawa tí Japan ní àwọn ọjọ́ mẹ́rin tí tẹlẹ, lẹyìn tí Taiwan tí kéde ní ọsẹ yìí.
Ìròyìn sọ pé ilé-iṣẹ́ ààbò tí Taiwan sọ ní ọjọ́ Ìṣẹgun Tuesday pé o tí ríi àwọn ọkọ ogún ojú-omí méjì tí Russia ní etikun ìlà-oòrùn rẹ̀, wọ́n sì ràn àwọn ọkọ ìjà Òfurufú àtí àwọn ọkọ ogún Ojú-Omí fún ìṣọ.
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Japan sọ ní oṣù tó kọjá pé àwọn ológun tí Russia àtí China ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ kàn ní àgbègbè Japan, èyí tó ń ṣé irọkẹ̀kẹ ẹrù fún ààbò orílẹ̀-èdè Japan.
Ìròyìn sọ pé Japan àtí Taiwan tí darapọ̀ mọ́ America àti àwọn alajọṣepọ rẹ̀ látí ṣé ijẹniniya nlá sí ilẹ̀ Russia lẹ́yìn ikọlù Ukraine ní ọdún tó kọjá.
Leave a Reply