Take a fresh look at your lifestyle.

Samson Siasia Ṣé Àyẹwò Gbàgede Bọ́ọ̀lù Sintetiki Kàn Ní Ìlú Abuja

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 301

Àgbábọ́ọ̀lù àti Olùkọ́ni àgbà fún Ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹlẹ rí, Samson Siasia tí ṣàbẹwò sí ilé-ìwé ‘School of The Hard knocks’ tó ṣẹṣẹ ṣé Turn-Back-Crime Synthetic Football Arena ní Abuja, Olú-ìlú Nàìjíríà.

Siasia tó ṣàbẹwò sí gbàgede náà ní ọjọ́ Àbámẹ́ta tún gbóríyìn fún Alákóso tí ilé-ìwé School of Hard knocks, Dókítà Jerry Akubo fún ṣiṣẹda ọnà tó gbà àwọn ọdọ kúrò ní ọnà ìparun.

Voice of Nigeria jábọ pé Ilé-ìwé tí Hard knocks SOHK Nàìjíríà jẹ́ ilé-ìwé ìtọ́sọ́nà ọkàn tó nílò àwọn eré ìdárayá, iṣawari ọpọlọ, àti àwọn iṣẹ́ tó dá lórí eré-ìdárayá láti ṣé ìyípadà ọpọlọ, àtí àlàáfíà fún gbogbo olufẹ.

Siasia wà nínú àwọn ẹgbẹ́ tó fí ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ibi-bọ́ọ̀lù afẹsẹgba náà ní Oṣù Kẹrin, fí ìdùnnú rẹ̀ hàn sí iṣẹ́ náà àti ìpele tó tí wà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button