Komisona àgbà tí United Nations fún àwọn tó ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọ́n (UNHCR), Filippo Grandi, rá ọ̀wọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó pààlà ibodè pẹ̀lú Sudan èyítí ogún tí ń já látí bí oṣù méjì sẹyìn látí “ṣí àwọn ààlà wọ́n sílẹ̀.”
Ó sọ èyí lẹ́yìn tó kéde pé ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù èèyàn tó sá kúrò lórílẹ̀-èdè náà nígbà tí àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ti sá kúrò nílùú náà.
Ogún Sudan tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dogún 15th Oṣù Kẹrìn láàrín ọmọ ogún Sudan, tí Gen. Abdel Fattah Al-Burhane, àti àwọn ológun àtìlẹ́yìn iyàrá tí (RSF), tí Gen. Mohamed Hamdane Daglo, èyí tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn tí pàdánù ẹ̀mí wọ́n gẹ́gẹ́ bí NGO ACLED ṣé sọ.
Gẹ́gẹ́ bí UN ṣé sọ, 25 mílíọ̀nù àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Sudan èyí tó jù ìdáméjì àwọn olùgbé Orílẹ̀-èdè náà ní báyìí ló nílò ìrànlọ́wọ́ ọmọnìyàn.
Ní ọjọ́ Aje, àwọn àgbègbè àgbáyé tí ṣé àdéhùn bílíọ̀nù kàn abọ dọla $1.5B látí ṣé ìrànlọ́wọ́ fún Sudan tó jẹ́ ìdajì òun tí á béèrè fún.
Leave a Reply