Ìfilọ́lẹ̀, Ìbúra Àti Yíyan Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Adebo Ogundoyin Wọlé Gẹ́gẹ́ Bíi Adarí Ilé Lẹ́ẹ̀kejì
Ile Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ ti yan ẹni tíì ṣe Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹsán, Adebo Edward Ogundoyin to n sojú Ẹkùn Ila Oòrùn Ìbàràpá gẹ́gẹ́ bíi Adari ilé fún sáà kejì.
Ìyànsípò lẹẹkeji yii ló wáyé nígbà tí ọkàn lára ọmọ ilé, Bamidele Adéọlá to n ṣojú Ẹkùn Iseyin/Itẹsiwaju dá àbá láti yan Adebo Ogundoyin gẹ́gẹ́ bíi Adarí ilé, nígbà tí Adebayo Babajide tó n sojú Ẹkùn Ariwa Ibadan II ṣìkejì àbá, nínú èyí tí gbogbo ọmọ ilé fara mọ́ àbá náà.
Bákan náà ní ọkàn lára ọmọ ilé, Razak Mabaje to n sojú Ẹkùn Ido dá àbá yíyan Abiodun Mohammed Fadeyi to n sojú Ẹkùn Ona Ara láti jẹ ìgbákejì Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá, nígbà tí Olusola Adéwálé Owolabi to n sojú Ẹkùn Ariwa Ila Oòrùn Ìbàdàn Kejì ṣìkejì àbá, ti gbogbo ile sí fara mọ àbá náà.
Nígbà tí o n sọrọ, ẹni tíì ṣe Akọwe ilé, Yetunde Awẹ to darí ètò ifilọlẹ ati Ìbúra fi àsìkò náà ki àwọn ọmọ ilé ti ìlú ṣẹṣẹ dibo yàn àti àwọn tó jẹ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Kẹsán ti ìlú tún dibo yàn, tó sì ka ọrọ àpilẹ̀kọ fún ètò ìfilọ́lẹ̀ àti ibura fún Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Lẹyìn tí ilé ti dá àbá láti tún yan Adebo Edward Ogundoyin (to je Adarí Ilé Kẹsán) gẹ́gẹ́ bíi Adari Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kẹwa àti igbákejì rẹ̀ Abiodun Mohammed Fadeyi, Akọwe ilé, Yetunde Awẹ kéde wọn fún ilé tó sì ṣe ètò ibura fún àwọn méjèèjì. Lẹyìn ètò yìí náà ni Adari ile ṣe ètò ibura fún àwọn ọmọ ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin tó kù.
Ṣáájú nínú ọrọ àpilẹ̀kọ rẹ̀, Adarí Adebo Ogundoyin sọ di mímọ pé òun gbà ìyànsípò lati tun darí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá pẹ̀lú èmi im’oore, tó sì fi tọwọtọwọ gbà ipò adari náà. O wa fi àsìkò náà dupẹ lọ́wọ́ Gómìnà Makinde tó sì fi àsìkò náà kíi káàbò sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó sì tún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ jakejado Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti gbárùkù ti wọ́n kí wọ́n lè ṣe àṣeyọrí.
Ogundoyin tún fi àsìkò náà dupẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, Olóyè Justina Ogundoyin tó ti di olóògbé fún akitiyan àti ìgbìyànjú rẹ̀ láti rí dájú pé oun dé ipò tó dé lónìí.
Bákan náà, o ṣàlàyé pé eléyìí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ọmọ ilé kan náà yóò dárí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin lẹẹmeji leralera. Ó wá fi àsìkò náà dà gbogbo ilé ati àwọn èèyàn tó péjú lójú wí pé àwọn yóò sa ipá wọn láti mọ lé ìpìlẹ̀ rere tí wọ́n ti fi lélẹ̀ lásìkò Ilé Ìgbìmọ̀ Kẹsán.
Ile ìgbìmò Aṣòfin Kẹsan ní o di tituka ni ọjọ Kẹsan Oṣù Kẹfà Ọdún yìí (09/06/2023).
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply