Ìbásepọ̀ láàrin Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà Àti Canada Lágbára si Lójúnà Àti Mú Ìgbòòrò Bá Ọrọ̀ Ajé
Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fi ìlàkààkà rẹ̀ léde lójúnà àti jẹ́ kí ìbásepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Canada fìdí múlẹ̀ sinsin láti mú ìgbòòrò bá ọrọ̀ ajé tí yóò sì se okùn-ǹ-fà fún ìdàgbàsókè àwọn ilé iṣẹ́.
Akọ̀wé àgbà ní ẹka Ilé-Isẹ́, Òwò àti Ìdókoòwò, Ọ̀mọ̀wé Evelyn N. Ngige ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí igbákejì asojú orílẹ̀ èdè Canada sí Naijiria, Teshome, ní ìlú Abuja.
Ọ̀mọ̀wé Ngige fi ìdánilójú hàn wípé, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti setán láti jẹ́ kí ìbásepọ̀ tí ó dán mọ́nrán wáyé láàrin orílẹ̀ èdè méjéèjì náà fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti ìmọ̀ ìgbàlódé.
Leave a Reply