Take a fresh look at your lifestyle.

Orilẹ̀-ède Egypt Dá Oníròyìn Al Jazeera Sílẹ̀ Kúrò Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

0 203

 

Oníròyìn Al Jazeera, Hisham Abdelaziz ni wọ́n ti dá sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́rin ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Egypt.
.
Àwọn ẹbí rẹ̀ jẹ̀rí sí wí pé òtítọ́ ni ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé, ó sì ti wà pẹ̀lú wọn ní ìlú Cairo.

Ọ̀gbẹ́ni Abdelaziz tó ń ṣiṣẹ́ fún ìkànnì
Mubasher ni wọn gbámú ní oṣù kẹfà ọdún 2019 nígbà tí ó rin ìrìn àjò láti Qatar lọ sí Cairo láti lọ bẹ ẹbí rẹ̀ wò .

Ó jẹ́ ọ̀kan lára oníròyìn Al Jazeera tí wọ́n yóò ti mọ́lé ní Egypt lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba kúrò lọ́wọ́ ààrẹ Mohamed Morsi tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2013.

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn oníròyìn Mubasher Al Jazeera méjì, Bahaa Eldin Ibrahim àti Rabie el-Sheikh sì wà lẹ́wọ̀n ní Egypt tí wọn kò tí dá sílẹ̀. Al Jazeera sì ti ń pè lemölemọ́ fún ìdásílẹ̀ tiwọn náà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button