Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje AFCON U-17: Ikọ̀ Morocco Lù Ikọ̀ South Africa Bí Ẹni Lu Aṣọ Òfì

0 247

 

Ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ agbábọ́ọ̀lù -Young Atlas Lions ti orílẹ̀-èdè Morocco lù Ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ -Amajimbos ti orílẹ̀-èdè South Africa ní ayò méjì sí òdo (2-0) nínú ayò méjì wọn ti ìpín B láti lè dúró sí òkè Tábìlì ténté tí Nàìjíríà sì ń tẹ̀lé wọn.

Ikọ̀ ti Nàìjíríà yóò kojú ikọ̀ Morrocco ní ọjọ́ Ọjọ́rú, ikọ̀ South Africa yóò kojú ikọ̀ ti Zambia.

Ayò Ikọ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú Ikọ̀ Morrocco yóò wáyé ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn úń ní aago méje aṣálẹ́ ti orílẹ̀-èdè yìí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button