Take a fresh look at your lifestyle.

Kamala Harris Sàbẹ̀wò Sí Ilẹ̀ Adúláwọ̀

0 244

Igbákejì Ààrẹ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Kamala Harris ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọlọ́ṣẹ̀ kan láti se àbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀ èdè ilè Adúláwọ̀ lójúnà àti faga-gbága pẹ̀lú orílẹ̀ èdè China nípa ìtànkálẹ̀ agbára.

 

Ìrètí wà pé Igbákejì Ààrẹ Harris yóò sàbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè Ghana, Tanzania àti Zambia tí yóò sì sèpàdé pọ̀ pẹ̀lú wọn lórí ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé, Ìpèsè oúnjẹ àti àlékún ní òǹkà àwọn ọ̀dọ́.

 

Lára àwọn ètò ìrìn àjò rẹ̀, yóò ní ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwon obìnrin onísòwò ní ìlú Accra àti Lusaka ní orílẹ̀ èdè Zambia láti se ìjíròrò lórí ìdàgbàsókè òwò síṣe.

 

Ìgbésẹ̀ náà wáyé láti fi ìdí ìbásepọ̀ tí ó wà láàrin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà múlẹ̀ sinsin nípasẹ̀ ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé àti orílẹ̀ èdè.

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button