Orílẹ̀ èdè bíi, Mozambique, Equador, Japan, Malta àti Switzerland darapọ̀ mọ́ àjọ aláàbò àgbáyé ( United Nation Security Council) gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ tuntun. Eléyìí tí yóò fún wọn ní ànfààní ọdún méjì láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà.
Orílẹ̀ èdè China, France, Russia, United Kingdom àti United States jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ẹ gbére fún àjọ náà, tí wọ́n sì ní agbára láti yí nǹkan padà.
Jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ aláàbò àgbáyé fún orílẹ̀ èdè kan jẹ́ àseyọrí àti àgbéga, yóò sì fún orílẹ̀ èdè náà ní ànfààní àti ìlẹ́nulọ́rọ̀ nínú ètò ààbò àti àlàáfíà ní àjọ àgbáyé.
Leave a Reply