Akin obìnrin tí ó jẹ́ ọdẹ, Aisha Bakari ti rí ìyànsípò gẹ́gẹ́ bíi adarí àwọn ọdẹ tí ó gbógun ti ìgbésùmọ̀mí àti ìgbénipa, (Directorate of Hunting and Forestry of the Nigerian Hunter and Forest Security Services, NHFSS).
Arábìnrin Bakari tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ “Sarauniya Baka” ti kó ipa ribiribi níbi ìgbógunti àwọn alákatakítí ikọ̀ “Boko Haram” ní ilà oòrùn Àréwá ( North East) ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Adarí àgbà àjọ HNFSS, ọ̀jọ̀gbọ́n Josua Osatimehin sọ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wípé, àgbéga náà tọ́, ó sì yẹ fún akíkanjú obìnrin náà, fún ìgbìyànjú àti ìlàkààkà rẹ̀ nípa gbígbógun ti àwọn alákatakítí àti agbésùmọ̀mí.
Nígbà tí ó ń fi ìdùnnú àti ìdúpẹ́ rẹ̀ léde, arábìnrin Bakari sọ wípé, ìpinnu òun láti ṣe iṣẹ́ náà wá látàrí èrò rẹ̀ fún ìdáàbò bo àwọn obìnrin àti ọmọdé kúrò lọ́wọ́ àwọn ajínigbé. O sì gbé oríyìn fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún akitiyan wọn.
Leave a Reply