Mínísítà fún ètò irinna lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mu’azu Sambo tí fí dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójú pé ètò ojú-irin tuntun yóò só gbogbo olú-ìlú ìpínlẹ̀ Nàìjíríà pọ̀.
Ọgbẹni Sambo ṣé ìdánilójú náà làkókò tó n sọ ọ̀rọ̀ níbí ayẹyẹ Ogún ọdún tí àwọn akẹkọ yunifásítì Igbinedion, Okada, ìpínlẹ̀ Edo, gúsù Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí mínísítà náà, “Ètò ojú-irin tuntun wà yóò só gbogbo àwọn olú-ìlú ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà, o tí pèsè ọnà àsopọ sí Ìlú Benin tẹlẹ lórí iṣẹ́ àkànṣe ojú-irin náà tó lọ láti Èkó sí Calabar.
“Iṣẹ́ àgbéṣe ibùdókọ ojú omí Benin tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Edo, tí n gbà àtìlẹ́yìn lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ igbokegbodo ọkọ ìjọba Àpapọ̀ àti àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn gbogbo láti ríi dájú pé o parí ní àsìkò.”
Kò kéré ní mẹ́tàlà (13) àwọn iṣẹ́ ọnà òpópó-ònà tí ìjọba àpapọ̀ tí wá ní ìpele ìparí èyí jẹ́ bí àwọn ẹrí àwọn àṣeyọrí tí ìṣàkóso yìí pẹ̀lú Ètò Ilé gbígbé tí Orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ìpinnu láti kojú ìṣòro àìrí légbèé.
Lekan Orenuga
Leave a Reply