Gbajúgbajà eléré ìdárayá obìnrin, Tobi Amusan ti wà lára àwọn márùn-ún tí wọ́n dábàá fún àmìn ẹ̀yẹ eré ìdárayá fún àyájọ́ eré ìdárayá ti àgbáyé tí ó ń bọ̀ lọ́nà.
Amusan fa akọ yọ níbi eré ìdárayá Oregon ti ọdún 2022, nígbà tí ó parí eré náà ní ìsẹ́jú àáyá méjìlá ó lé díẹ̀ (12.06s) tí ó sì gba àmìn ẹ̀yẹ góòlù (gold).
Wọ́n ti fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ bíi Shelly-Ann Fraser-Pryce of Jamaica, Kimberly Garcia of Peru USA’s Sydney Mclayghlin and Venezuela Yulimar Rojas.
Leave a Reply