Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Pàdà Sí Abùjá

0 229

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí pàdà sí Abùjá lẹyìn tó kópa nínú ìpàdé World Bio Summit ní Seoul, orílẹ̀-èdè South Korea.

O balẹ gudẹ sí Papakọ Òfurufú International Nnamdi Azikiwe ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ Ẹtì.

Lára àwọn tí wọ́n pàdé Ààrẹ ní Olórí òṣìṣẹ́ Ààrẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari àti Mínísítà tí Federal Capital Territory, Mohammed Bello àti àwọn olórí àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò.

L’akoko tó ń sọrọ ní ìpàdé náà, o ṣàfihàn bí Nàìjíríà tí ṣé múra sílẹ láti di ìbùdó ìlé-íṣẹ́ àjẹsára lọpọ yanturu.

Bákan náà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti South Korea buwọ́lù ìwé àdéhùn Láàrín orílẹ-èdè méjèèjì lórí iṣẹ àtúnṣe ilé-iṣẹ́ ifọpo Kaduna àti Warri.

Bákan náà ló tún ṣé ìpàdé pẹlú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè South Korea níbí tó tí gbà wọ́n lamọran láti jẹ́ aṣojú réré orílẹ̀-èdè yìí.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button