Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Fèsì Sì Ìdájọ́ Ilé-Ẹ̀jọ́ lórí Ẹjọ́ Kanu

0 297

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé, àwọn yóò ṣé àṣàyàn àwọn ìlànà tó dìrọ̀ mọ̀ ìdájọ ṣiṣi olórí àwọn Indigenous peoples of Biafra (IPOB) ọgbẹni Nnamdi Kanu sílẹ̀ tí ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣé ní Ọjọ́bọ̀.

Agbẹjọro ijọba ati Mínísítà fún Ìdájọ́, Abubakar Malami nínú ìdáhùn rẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ rẹ̀ Umar Gwandu sọ pé, àwọn yóò ló awọn àṣàyàn òfin tó wà ní iwájú àwọn lọ́nà tó yẹ, awọn yóò sì kéde rẹ fún àwọn ará ìlú.

Àlàyé náà ṣé àkíyèsí pé, ẹjọ́ kàn péré ní wọn gbé lọ síwájú ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ilé-ẹjọ́ náà sì dajọ le lórí. O sí ràn àwọn ará ìlú létí pé, ẹjọ́ bi Kanu ṣé sá kúrò nílùú ṣì wà nílẹ̀ fún ìdájọ.

“Ìjọba àpapọ̀ yóò pàdà lọ sí ilé-ẹjọ́ fún bí Kanu ṣé sá kúrò nílùú lẹyìn tí ilé ẹjọ́ dáa sílẹ̀ tẹlẹ rí àti àwọn ẹka tó wà nílẹ̀ ṣáájú ìdásílẹ̀ náà.”

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button